UPL Share Price: N3.5 As at 26-11-2024 | Careers | Complaint

Shop

Taiwo ati Kehinde Iwe Kin in ni – (New Edition)

2,400

̣̀wọ́ ìwé Táíwò àti Kéhìndé Ìwé Kìn-ín-ní títí dé ìwé kẹfà ti jẹ́ ìlú mọ̀-ọ́n-ká fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá ọjọ́ ti pẹ́. Àpilẹ̀ṣe Ọ̀tun kẹrin fún UBE yìí kò ṣàìfọ́ ìró èdè ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílò fún ìtẹ̀síwájú ẹ̀kọ́ wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ títí dé ípele kẹfà ẹ̀kọ́ wọn sí wẹ́wẹ́.

Gbogbo ìmọ̀ tí akẹ́kọ̀ọ́ ìpele yìí nílò gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí àwọn ìgbìmọ̀ tí ìjọba yàn láti ṣe àtúnṣe ọ̀nà kíkọ Yorùbá sílẹ̀ ti fi lélẹ̀ àti ìmọ̀ràn àwọn ìgbìmọ̀ tí ìjọba yàn láti ṣe káàárọ̀-o-ò-jíre tún fi síwájú ìjọba lẹ́yin àṣàrò tiwọn lórí bí i: dídá orúkọ nǹkan inú kíláàsì, ṣíṣe nǹkan, òǹka oókan dé ẹẹ́wàá, álífábẹ́ẹ̀tì Yorùbá, kíkọ́ ìró álífábẹ́ẹ̀tì, orin ìrẹmọlẹ́kún, abíídí aláwòrán, ìkíni àti ìdáhùn, ìmótótó ara ẹni, ìwà rere: ìbọ̀wọ̀fágbà, ìmótótó àyíká, àrọ̀fọ̀ kéékèèké, àkókò òjò, àkókò ẹ̀ẹ̀rùn, kòkòrò tó léwu, abbl. ni a ṣe àkójọ wọn.

Ọ̀rọ̀ akọ́nilẹ́nu lóríṣiríṣi tún wà fún ìdárayá àwọn èwe. Ìwé ọ̀tun yìí ti yàtọ̀ gédégédé sí àwọn èyí tí a ti ní tẹ́lẹ̀. Àwòrán tí ó fanimọ́ra ni a fi ṣe àpẹẹrẹ àwọn nǹkan àrídìmú ẹ̀kọ́ inú ìwé yìí.

Àwòrán lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan tí ó lè fa ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ sí ẹ̀kọ́ nípa nǹkan àyíká ẹni àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ní ìbámu pẹ̀lú kọ̀ríkúlọ́ọ̀mù ìkọ́ni tuntun ní èdé yorùbá, ní ìpele ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ni a ti ṣe àfikún rẹ̀ sínú ìwé yìí.

Iṣẹ́ ṣíṣe tía fi kún iwé yìí fún àwọn olùkọ́ àti òbí láàyè láti mọ̀ bóyá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ ohun tí a kọ́ wọn. Ó sì mú ìrọ̀rùn bá olùkọ́ láti ṣe ìgbéléwọ̀n àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́yìn ìdánillẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan.

Ògúnná gbòǹgbo tí í dátọ́ lẹ́nu ìgbín ni àwọn òǹkọ̀wé tí wọ́n jùmọ̀ ṣiṣẹ́ yìí lẹ́yin ìfilọ́lẹ̀ tí olóògbé Olóyè T T Ṣólárù tis ̣e nípa ìwé yìí kí ó tó papòdà.

Àgékúrú, àtúntò, àfikún ìmọ̀ àti àyọkúrò tí ó yẹ níbi gbogbo ni àwọn akọ́ninímọ́, olùkọ́ èdè wọ̀nyi tis ̣e lórí ìwé yìí kí ó lè ba à bá ìgbà mu.
Oyin mọmọ ni!

wws Debo / Pre-sale Questions Need Help? Contact Us via WhatsApp
ISBN: 9789789401253 Categories: , Tags: , , ,

Additional information

Weight 0.2 kg
Dimensions 9.75 × 7.25 cm

Reviews

There are no reviews yet.

Be the first to review “Taiwo ati Kehinde Iwe Kin in ni – (New Edition)”

Your email address will not be published.

234-8110713098 (234-8008775264) Toll free info@universitypressplc.com
WeCreativez WhatsApp Support
Our customer support team is here to answer your questions. Ask us anything!
👋 Hi, how can I help?